2 Kings 7:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin náà lọ títí dé odò Jọdani. Ní gbogbo ojú ọ̀nà náà ni wọ́n ti ń rí àwọn aṣọ ati àwọn ohun ìjà tí àwọn ará Siria jù sọnù nígbà tí wọn ń sá lọ. Wọ́n sì pada wá ròyìn fún ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si tọ̀ wọn lẹhin de Jordani: si wò o, gbogbo ọ̀na kún fun agbáda ati ohun elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn. Awọn onṣẹ si pada, nwọn si sọ fun ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jọ́dánì, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Ṣíríà gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránsẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba.