2 Kings 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Samaria sì tú jáde láti lọ kó ìkógun ní ibùdó ogun àwọn ará Siria. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLUWA ti sọ, wọ́n ta òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan ní ìwọ̀n ṣekeli kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Ṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún Sẹ́kẹ́lì kan, àti òsùnwọ̀n báálì méjì ní Ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ.