2 Kings 7:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí nígbà tí eniyan Ọlọrun sọ fún ọba pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, lẹ́nu bodè Samaria, àwọn eniyan yóo máa ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan,”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi enia Ọlọrun na ti sọ fun ọba, wipe, Oṣùwọn barle meji fun ṣekeli kan, ati òṣuwọn iyẹfun kikunná kan, fun ṣekeli kan, yio wà ni iwòyi ọla ni ẹnu bodè Samaria:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ti sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyan Ọlọ́run ti ṣọ fún ọba: “Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun ni a ó ta nì Ṣékélì kan àti òsùnwọ̀n méjì báálì ní Ṣékélì kan ní ẹnu ọ̀nà ibodè Ṣamáríà.”