2 Kings 7:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Ǹjẹ́ èyí lè ṣẹ, bí OLUWA tilẹ̀ rọ̀jò àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá.” Eliṣa sì dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rẹ rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijòye na si da enia Ọlọrun na li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, nisisiyi, bi Oluwa tilẹ ṣe ferese li ọrun, iru nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìjòyè náà ti wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Wò ó, kó dà ti OLÚWA bá sí fèrèsé ní ọ̀run, ṣé èyí lè ṣẹlẹ̀?” Ènìyàn Ọlọ́run sì ti dáhùn pé, “kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò fi rí i, Ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ ọ̀kan kan lára rẹ̀.”