2 Kings 7:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?” Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ sé ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wòó, tí OLÚWA bá tilẹ̀ sí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?” “Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ,” Èlíṣà dáhùn, “ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkankan lára rẹ̀!”