2 Kings 7:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí àwa bá wí pé, ‘Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀,’ àwa yóò sì kú. Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Síríà kí àwa kí ó sì tẹríba. Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú.”