2 Kings 7:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí OLÚWA jẹ́ kí àwọn ará Síríà gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Ísírẹ́lì ti bẹ ogun àwọn Hítì àti àwọn ọba Ígíbítì láti dojúkọ mú u wá!”