2 Kings 7:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni nwọn dide, nwọn si salọ ni afẹ̀mọjumọ, nwọn si fi agọ wọn silẹ, ati ẹṣin wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ani, ibùdo wọn gẹgẹ bi o ti wà, nwọn si salọ fun ẹmi wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.