2 Kings 7:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati adẹtẹ̀ wọnyi de apa ikangun bùdo, nwọn wọ inu agọ kan lọ, nwọn jẹ, nwọn si mu, nwọn sì kó fadakà ati wura ati agbáda lati ibẹ lọ, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́; nwọn si tún pada wá, nwọn si wọ̀ inu agọ miran lọ, nwọn si kó lati ibẹ lọ pẹlu, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.