2 Kings 7:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Oni yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa si paamọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjayà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.”