2 Kings 8:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí OLÚWA ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”