2 Kings 8:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?” Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kí ni ó dé tí OLÚWA mi fi ń sunkún?” Hásáélì bèèrè. “Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”