2 Kings 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀. Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li o lọ kuro lọdọ Eliṣa, o si de ọdọ oluwa rẹ̀; on si wi fun u pe, Kini Eliṣa sọ fun ọ? On si dahùn wipe, O sọ fun mi pe, Iwọ o sàn nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Hásáélì fi Èlíṣà sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí Bẹnihádádi bèèrè, “Kí ni ohun tí Èlíṣà sọ fún ọ?” Hásáélì dá a lóhùn, “Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́.”