2 Kings 8:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé.