2 Kings 8:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joramu ọba si pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ti ṣa a ni Rama, nigbati o mba Hasaeli ọba Siria ja. Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu ọmọ Ahabu ni Jesreeli nitoriti o nṣe aisàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ọba Jórámù padà sí Jéṣérẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Síríà ti jẹ níyà lórí rẹ̀ ní Rámò ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hásáélì ọba Árámù. Nígbà náà Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jésérẹ́lì láti lọ wo Jórámù ọmọ Áhábù nítorí tí ó fi ara pa.