2 Kings 8:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.