2 Kings 8:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe bi o ti nrò fun ọba bi o ti sọ okú kan di ãyè, si kiyesi i, obinrin na, ẹniti a sọ ọmọ rẹ̀ di ãyè kepè ọba nitori ilẹ rẹ ati nitori ile rẹ̀. Gehasi si wipe, Oluwa mi, ọba, eyi li obinrin na, eyi si li ọmọ rẹ̀ ti Eliṣa sọ di ãyè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Gèhásì ti ń sọ bí tí Èlíṣà ṣe jí òkú di alàyè, obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí Èlíṣà ti dá padà sí ayé wá láti bẹ ọba fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀. Gèhásì sì wí pé, “Obìnrin náà nì yí OLÚWA mi ọba, ọmọkùnrin rẹ náà nìyí tí Èlísà ti jí dìde sí ayé.”