2 Kings 8:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà, ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ọba bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó fún obinrin náà ní gbogbo ohun tíí ṣe tirẹ̀ pẹlu gbogbo ohun tí wọ́n ti kórè ninu oko náà, láti ìgbà tí obinrin náà ti fi ìlú sílẹ̀ títí di ìgbà tí ó pada dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọba si bère lọwọ obinrin na, o rohin fun u. Ọba si yàn iwẹ̀fa kan fun u, wipe, Mu ohun gbogbo ti iṣe ti rẹ̀ pada fun u, ati gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ silẹ titi di isisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba bèèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un. Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkòyí.”