2 Kings 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hasaeli di ogoji ẹrù ràkúnmí tí ó kún fún oniruuru ohun rere tí ó wà ní Damasku, ó lọ bá Eliṣa. Nígbà tí Hasaeli pàdé rẹ̀, ó sọ pé, “Iranṣẹ rẹ, Benhadadi, ọba Siria, rán mi láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá òun óo yè ninu àìsàn òun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Hasaeli lọ ipade rẹ̀, o si mu ọrẹ li ọwọ rẹ̀, ani ninu gbogbo ohun rere Damasku, ogoji ẹrù ibakasiẹ, o si de, o si duro niwaju rẹ̀, o si wipe, Ọmọ rẹ Benhadadi ọba Siria rán mi si ọ, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”