2 Kings 9:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli, kò sí ẹni tí yóo sin òkú rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀rọ̀ náà tán, ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún Jésébélì, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jésírẹ́lì, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkúrẹ̀.’ ” Nígbà náà ó sí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ.