2 Kings 9:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jehu pada sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé kò sí nǹkan? Kí ni ọkunrin bíi wèrè yìí ń wá lọ́dọ̀ rẹ?” Jehu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ọkunrin náà, ati ohun tí ó sọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jéhù jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?” Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jéhù fèsì.