2 Kings 9:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.” Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jésérẹ́lì, rí ọ̀wọ́-ogun Jéhù tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Jórámù pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”