2 Kings 9:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jéhù ọmọ Nímsì, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.”