2 Kings 9:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Jórámù pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Jórámù ọba Ísírẹ́lì àti Áhásáyà ọba Júdà, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Nábótì ará Jéṣírẹ́lì.