2 Kings 9:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?” Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jórámù rí Jéhù, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jéhù?” “Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jéhù dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti mọ̀mọ́ rẹ Jésébélì di púpọ̀?”