2 Kings 9:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
pé, ‘Mo rí i bí o ti pa Naboti ati àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá, dájúdájú n óo jẹ ọ́ níyà ninu oko kan náà.’ Nítorí náà gbé òkú rẹ̀ jù sinu oko Naboti gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni OLÚWA wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA.”