2 Kings 9:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Ahasaya rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà Beti Hagani lọ. Jehu bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọkunrin rẹ̀ pé kí wọ́n ta á lọ́fà! Wọ́n sì ta á lọ́fà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní ọ̀nà Guri lẹ́bàá Ibileamu, ó sá lọ sí Megido, níbẹ̀ ni ó sì kú sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Áhásáyà ọba, Júdà rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Bẹti-Hágánì. Jéhù sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n sá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Gúrì lẹ́bà a Íbíléámù, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Mégídò, ó sì kú síbẹ̀.