2 Kings 9:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì sin ín pẹ̀lú, bàbá a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì.