2 Kings 9:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Èmi fi àmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.’ Nígbà náà, sí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!”