2 Kings 9:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nwọn si tun pada wá, nwọn si sọ fun u. On si wipe, Eyi li ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀ ara Tiṣbi wipe, Ni oko Jesreeli li awọn aja yio jẹ ẹran-ara Jesebeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n padà lọ sọ fún Jéhù, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà ará Tíṣíbì wí pé: Ní orí oko Jésérẹ́lì ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran ara Jésébélì.