2 Kings 9:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.” Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?” Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí. “Fún èwo nínú wa?” Jéhù béèrè. “Fún ọ, Alákóso,” Ó dáhùn.