2 Kings 9:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhù dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jéhù; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn OLÚWA Ísírẹ́lì.