2 Kings 9:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ìdílé Ahabu ni yóo ṣègbé, n óo sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin tí wọ́n wà ninu ìdílé náà, ati ẹrú ati ọmọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori gbogbo ile Ahabu ni yio ṣegbé: emi o si ké gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Ahabu ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ilé Áhábù yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Áhábù gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí òmìnira.