2 Peter 1:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsinmi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò subú.