2 Peter 1:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlìí dunjúdunjú síi, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsí gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ́ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín.