2 Peter 2:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ. Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n páàpáà àwọn tí ó ń tọ ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.