2 Peter 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ohun tí kò yé wọn. Wọ́n dàbí ẹranko tí a kò lè tù lójú, àwọn ẹ̀dá aláròse, tí a dá láti máa mú pa, bí ẹranko ni wọ́n yóò sí sègbé pẹ̀lú.