2 Peter 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olúgbála wá Jésù Kírísítì, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a buru jú ti ìṣáájú lọ.