2 Peter 2:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Nóà mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn.