2 Peter 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀ gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́ iwe mimọ́ iyoku, si iparun ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tí ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn ṣọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lọ́, bí wọ́n ti ń lo ìwé-mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.