2 Peter 3:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.