2 Samuel 1:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti fún àwọn ọmọ ogun OLÚWA, àti fún àwọn ilé Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.