2 Samuel 1:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ijọ kẹta, si wõ, ọkunrin kan si ti ibudo wá lati ọdọ Saulu; aṣọ rẹ̀ si faya, erupẹ si mbẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati on si de ọdọ Dafidi, o wolẹ, o si tẹriba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Ṣọ́ọ̀lù, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.