2 Samuel 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ̀yin òkè Giliboa, kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí, bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín, kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa, nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà; a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ̀yin òkè Gílíbóà, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni aṣà alágbára ti ṣègbé, aṣà Ṣọ́ọ̀lù, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.