2 Samuel 1:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.” Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si tun bi lere wipe, Ọràn na ti ri? emi bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahun pe, Awọn enia na sa loju ijà, ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ si kú pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jónátanì sì kú pẹ̀lú.”