2 Samuel 1:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.