2 Samuel 10:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn si sá niwaju Abiṣai, nwọn si wọ inu ilu lọ. Joabu si pada kuro lẹhin awọn ọmọ Ammoni, o si pada wá si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì sì ríi pé àwọn ará Síríà sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Ábíṣáì, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Jóábù sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ámónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù.