2 Samuel 10:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a sọ fun Dafidi, o si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si wá si Helami. Awọn ara Siria si tẹ́ ogun kọju si Dafidi, nwọn si ba a jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a sọ fún Dáfídì, ó sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì, wọ́n sì wá sí Hélámì, Àwọn ará Síríà sì tẹ́ ogun kọjú sí Dáfídì, wọ́n sì bá a jà.