2 Samuel 10:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Siria si sa niwaju Israeli; Dafidi si pa ninu awọn ara Siria ẽdẹgbẹrin awọn onikẹkẹ́, ati ọkẹ meji ẹlẹṣin, nwọn si kọlu Ṣobaki olori ogun wọn, o si kú nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Síríà sì sá níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa nínú àwọn ará Síríà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sóbákì olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ́.