2 Samuel 10:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati gbogbo awọn ọba ti o wà labẹ Hadareseri si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ba Israeli lajà, nwọn si nsìn wọn. Awọn ara Siria si bẹ̀ru lati ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadésérì sì ríi pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Ísírẹ́lì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ará Síríà sì bẹ̀rù lati máa ran àwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́ mọ́.